ṢÓKÍ ÌRAN KEJÌLÁ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE TWELFTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Ara Ṣọlá kò yá. Lẹ́yìn àyẹ̀wo nílé ìwòsàn, dọ́kítà fi yé wọn pé Ṣọlá ti lóyún. Inú Fẹ́mi dùn gidi gan ni. Ṣọlá àti Kúnbi ṣì ń bá ọ̀rẹ́ wọn lọ. Amọ́ Kúnbi ń fi ìbànújẹ́ lóri ìlọsíwájú rẹ̀ pamọ́ fún Ṣọlá.

 

ṢÓKÍ ÌRAN KẸTÀLÁ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE THIRTEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Fẹ́mi wá bá Ṣọlá nílé lẹ́yìn tí ó ṣetán níbi iṣẹ́. Ó ṣàlàyé fun pé management course ọdún méjì kán wà tí òun kọ̀wé fún ní University of London lati bí ọdún méjì sẹ́yìn. Wọ́n ṣèṣè fi lẹ́tà ránṣé pé òun ni. Ó ní òun kò rò pé òun yòó lọ nitorí ipò tí Ṣọlá wà àfi tí Ṣọlá bá tẹ̀lé òun. Ṣọlá dáhùn pé ìyẹn kò ní lè ṣééṣe nítorí àgùnbánirọ̀ òun tí yòó bẹ̀rẹ̀ ní oṣù náà. Fẹ́mi sọ fun pé bí ó bá tẹ̀lé òun lọ, yóò ní ànfàní àti bímọ sílu òyìnbó, yòó sì padà wá ṣe àgùnbánirọ̀ rẹ̀. Ó ní kó máa mikàn nipa enití yòó tọ́jú ọmọ nítori òun yòó ránṣé sí Màmá òun àti tí Ṣọlá tó bá bímọ tán. Ṣọlá náà sì gbà. Ìmúra bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.