ṢÓKÍ ÌRAN OGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE TWENTEITH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Lọ́jọ́ kan, Kúnbi wà nílé ìdáná, Fẹ́mi ń wo bọ́ọ̀lù ní pálọ̀. Jùwọ́n, ọmọ rá kòrò lọ sí yàrá ibùsùn àwọn òbí rẹ̀, ó sì ń fi bọ́ọ̀lù rẹ̀ ṣeré. Ṣàdédé ni bọ́ọ̀lù fò lọ sábẹ́ bẹ́ẹ̀dì. Jùwọ́n tẹ̀lẹ, ó rí ìgò funfun kan, ó sì fáà sita. Ó fi ń ṣeré, à ṣé ògun àtijọ́ tíya rẹ ṣe ni. Ó fi ń ṣeré, ó gba mọ́lẹ̀,ìyẹn sì fọ́. Bí ó ṣe fọwọ́ kan àdó inú rẹ̀ ni o kígbe tí ó si nà gbalaja sílẹ̀.

Fẹ́mi sá lọ síbẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ti ń tú jade lati ẹnu ọmọ, òkú rẹ̀ níwọn gbé dé ilé ìwòsàn. Kúnbi gbàgbé ìkìlọ bàbá pé kò gbọdọ f’ọwọ́ kan òkú,kíá ni ògun ká lójú Fẹ́mi. Kúnbi bẹ̀rẹ̀ sí ní kà bòròbòrò. Fẹ́mi gbe lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ, ọ́ sì gba Nàìjíríà lọ láì sọfún ẹnikẹ́ni. Nígbàtí ó dé ilé àwọn òbí rẹ̀, àwọn òbí rẹ̀ tí mọ̀ pé ògun ló de ọmọ àwọn tẹ́lè pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń jade lẹ́nu rẹ̀. Ó ròyìn fún wọn pé gbogbo nǹkan tí Kúnbi ṣe, àjọmọ̀ òun àti ìyá rẹ̀ ni.

Àwọn òbí rẹ̀ sọfun pé kó dúrọ́ lọ́dọ̀ àwọn torí Ṣọlá àti àwọn ìbejì rẹ̀ kò ní pé dé. Nígbàtí Ṣọlá dé pẹ̀lú ìbẹjì, ó kọ́kọ́ dákú lọ́. Ó jí lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà. “Onkú” làwọn ìbejí ń pe Fẹ́mi, olóyè ló ṣẹ̀ẹ̀ṣè sọfun wọn pé bàbá wọn ni. Fẹ́mi kó ẹjọ́, ó ròó fún Ṣọlá, àánu ọmọ Kúnbi ṣe Ṣọlá, ó sì dún-ùn bákan náà pé Kúnbi ṣe adúrú nǹkan bẹ́ẹ̀.O ní, “Haa! Ẹ wojú ayé! Ọ̀rẹ mí”

ERÉ PARÍ

Comments are closed.