Aṣọ Rírán Ní Orílè Èdè Nàìjíríà

Lati ọwọ́ Hassan Abdulbaqi

 

Iṣẹ́ adúláwọ̀ ni iṣẹ aṣọ híhún àti rírán kí àwọn òyìnbò tó dé. Kí òyìnbo tó dé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni iṣẹ́ aṣọ rírán ti gòkè, kò sì kí ń ṣe àwọn òyínbó ló la adúláwò lójú lóri aṣọ wíwọ̀ àti aṣọ rírán. Kódà, àwọn tí ń gbé ní àfin ọba máa ń ni aránṣọ tiwọn bákan náà ni ti bọ̀rọ̀kíní. Gbogbo aṣọ wọn máa ń wà ní ìbámu pẹ̀lú ibi tí wọ́n fẹ́ wọ irúfẹ́ aṣọ náà lọ àti iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ fi ṣe. Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà ní òkè dé ibi pé àkọsílẹ̀ wà pé wọn máa ń kó aṣọ híhun lati ọ̀dọ̀ àwa Yorùbá ló sí Yúróòbù bí ọdún ẹgbẹ̀rún mẹrin sẹ́yìn.

Yàtọ̀ sí iṣẹ́ àgbè àti kátà-kárà, Yorùbá gbajúmọ̀ níbi iṣẹ́ ọnà ní sẹ́ntúrì òkandínlógún. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ọnà bí aṣọ híhun, àgbẹ̀dẹ, mímọ, ẹní ṣíṣe àti apẹ̀rẹ. Irú ìdàgbasọ́kẹ̀ yìí ní ilapa tó pọ̀ nínu àwọn ìlú Yorùbá àti ìletò. Àwọn ìlú tí irú èléyìí ti gbajúmọ̀ ni Ìsẹ́yìn, Ọ̀yọ́, Ṣaki, Igboho, Èkìtì, Ìjẹ̀bú-Òde, Abẹ́òkúta àti Ìlọrin. Èyí fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínu ìwádìí arábìnrin Angela Sancartier (2003) tí ó rí àkọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àdìrẹ dé ìlú Abẹ́òkúta lati bí ọgọ́rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn. Ìdí nìyìí tí àwọn Yorùbá ṣe máa ń sọpé, “kí òyìnbọ́ tó gòkè, kì í ṣe ewé ọ̀gẹ̀dè ni ẹ̀dá fi ń ṣe aṣọ.”

Ìwádìí Barth (1851) fihàn pé aṣọ àdìrẹ àti aṣọ híhun ní ṣíṣe àti ní rírán ti wà ní ìlú Kano ní nǹkán bi 1590. Àǹkàrá pẹ̀lú àwọn aṣọ tí o gbajúgbajà láàrín àwọn Yorùbá. Ayébáyé náà ni ìlo jákán gẹ́gẹ́bí ìwádìí fihàn ní Núpé àti ilẹ̀ Hausa. Ilẹ̀ Hausa, pàápàá jùlọ ìlú Kánò, ni wọn ti máa ń ko àwọn ohun èlò tí àẃọn Yorùbá bùkátà sí. Lati ìbẹ̀rẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá ni iṣẹ́ àgbẹ̀ tí bẹrẹ̀, tíwọn sí máa ń gbin òwú-akese (Gossypium herbaceum) àti owú Itutu (Gossypium arboretum). Àmọ́, òwú-akese (Gossypium herbaceum) ní ó gbé pẹ́lí jù nítorí ó ní àbùdá àti ṣe aṣọ gidi àti pé kòkòrò kò lè kùn-ún bí ti ìkejì. Baikie (1856) sọpé àwọn Elugwu IIho ní ilẹ̀ Íbò lápaapọ̀ àti àwọn tí ń gbé ní ìletò ní ìlú Ònitsha máa ń hun aṣọ. Àlàyé Equaino lóri ìrírí rẹ̀ ní àárín sẹ́ńtúrì kẹjọdínlógún pẹ́ kìkì iṣẹ́ tí àwọn obìnrin ń ṣe ni aṣọ híhun, tíwọn máa padà pa láró, kíwọn tó sọ di aṣọ wíwọ̀. Nígbàtí ọdún 1800 ń lọ ṣí òpin ní àṣà kí a máa kó aṣọ wọlẹ́ lati òkè òkun ti bẹ̀rẹ̀.

Nígbà tí àwọn òyìnbó dé, ìgbìyàǹjú àti ṣe àmúpé àṣà ìbílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmúra sọnù. Àṣà àti ìgbàgbọ́ àwọn òyìǹbó lórí ìmúra borí ti àwọn adúláwọ̀, eléyìí kò sì ya ìmúra sí ọ̀tọ̀. Ọ̀nà dí mọ́ àwọn tí ń rán aṣọ ìbílẹ̀ nítorí òkùtà. Aṣọ ìbílẹ̀ sábà máa ń fi irúfẹ́ ikọ̀ tí èèyàn jẹ́, ó sì tún máa ń fi ìjákọ àti ìjábo hàn. Fún àpẹẹrẹ, ìmúra pẹ̀lú wíwọ aṣọ ìbílẹ lè fi èèyàn hàn gẹ́gẹ́bí ará Eastern Nigeria yàtọ̀ sí Northern Nigeria tàbí Western Nigeria. Ní àfikún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú kéré aṣọ ìbílẹ̀. Eléyìí dènà di ìdàgbàsókè aṣọ ìbílẹ̀ títí di ìgbà tí àwọn òyìnbó fi lọ. Kódà, ó ti di aṣa fún àwọn èèyàn lati ṣe ìrìnàjò lọ sí òkè òkun, lati lọ ra aṣọ fún wíwọ̀ àti títà. Eléyìí ń ṣẹlẹ̀ títí wo àsìkò tí orílè Nàìjíríà gba òmìnira títí di ìgbà tí odún 1990 fi ń lọ sí òpin. Láarín ìgbà yíí náà niwọ́n gbé FADAN (The Fashion Designers Association of Nigeria) kalẹ̀ ní odún 1989. Aṣọ ìbílẹ̀ kò sí ní ọjà bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ti fi iṣẹ́ àgbẹ̀ sílẹ̀, èyítí ó fa ìfàsẹ́yìn nínu òwú ṣíṣe.

Níbi 1950 sí 1960, ó fẹ́rẹ̀ lè máà sí obìnrin tí kì í wé gèlè. Àsìkò tí Nàìjíríà gba òmìnira ní 1960 gan-an ni ìlo gèlè gbajúmọ. Oríṣiríṣi àrà ni oníkálukú ń fi gèle e rẹ̀ wé. Gèlè náà ni àwọn èèyan fi gbé oríyìn fún olóògbe Flora Azikwe, ìyẹn aya ààre tẹ́lẹ̀rí, Nnamdi Azikwe. Títí di ìgbà ayé Johnson Aguiyi-Ironsi, Yakubu Gowon, Eko ́ Bridge àti NEPA, ìyẹn àjọ tí ń bójútó iná nígbà náà. Ní nǹkan bí ọdún 1960 àti 1970, àwọn gbajúgbajà aránṣọ pọ̀ jántì rẹrẹ, díè nínu wọn ni Ògúndẹ̀rò, Fágbohùn àti Láí Olúmegbon ní Yába. Èkó àti Ìbàdàn ní ó gbáwájú ní ìdí iṣẹ yìí nítorí ibẹ̀ ni àwọn aránṣọ tíwọ́n lọ kọ́ iṣẹ́ ní ìlú Ọba wà. Ìpadàbọ̀ akọrin Fẹlá Aníkúlápò Kútì náà lapa nínu aṣọ wiwọ awọn tiwọn fẹran rẹ nigba naa. Àwọn aṣọ bí “high waisters”” ṣòkòtò àti ìfi aṣọ orun silẹ lai ka gbajumọ nigba náà. Àwọn àrà aṣọ tí wọ́n pè ní Obey The Wind tabi Keep Lagos Clean náà ti gbòde. Oge náà ni kí awọn okùnrin fi irun wọn sílẹ̀ ní kikun àti wíwọ bàta I Swear to God, èyí tí ó fẹ níwájú, tí ó sì kéré lẹ́yìn

Ìdàgbàsókè tún bẹ̀rẹ̀ sí í bá wíwọ aṣọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú ìpolongo tuntun lóri àṣà adúláwọ̀ ní ìgbà tí 1990 gbẹ́nu lọ sí ìparí. Eléyìí sì jẹ́ kí àwọn ìjọba gbà kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa wọ aṣọ ìbílẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ Jimo. Ìlo aṣọ ìbílẹ̀ tún gbajúmọ̀ fún ọ̀ṣọ́ ilé, ara abbl. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti bẹrẹ̀ sí ní fi aṣọ mútìẹ sílẹ̀. Eléyìí fún àwọn ilé iṣẹ́ aránṣọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àgbeyèlé wípé ọjọ́ ọla aṣọ rírán bọ wá dára.

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìpolówó aṣọ àti ìfaṣọhàn ni ó wáyé lati ọwọ́ àwọn aránṣọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lágbáyé. Kódà, àrà tí àwọn aránṣọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ń fi aṣọ da ń jẹ́ àríwòye fún àwọn aránṣọ tókùn lágbáyé gégébí Gucci, eléyìí si fi ara hàn nínu bí àfihàn iṣẹ àwọn aránṣọ ṣe ń fi ara hàn nínu magasínì oge lágbáyé. Kárà-kátà àwọn ọjà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní orí ìtàkùn àgbáyé àti àfihàn wọn ní orí ẹ̀rọ ayélujára náà kò kó kékeré nínu ìdàgbàsókè aṣọ rírán àti aṣọ títà. Lára àwọn nǹkan tí ó tún fa ìdàgbàsókè yìí ni ti ìpolongo kí àwọn èèyàn máa lo àwọn nǹkan orílẹ èdè wọn. Ààjo tí ń ṣe eré tíátà (Nollywood) náà kún ìdàgbàsókè yìí lọ́wọ́.

Ayé àtijọ́ ni àwọn òbí máa ń ti ọmọ wọn sí ìdí iṣẹ́ ìránṣọ nígbàtí wọn kò bá ní owó àti rán wọn ní ilé ìwé. Ìdàgbàsóké ńlá ti dé bá iṣẹ́ yìí, dé bi wípé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti ṣe tán ní ifáfitì gan-an ti ń kọ́ iṣẹ́ yìí. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn aṣọ ní orílè Nàìjíríà ti gbalẹ̀ débi wípé, káàkiri ayé niwọ́n ti n fi wọ́n hàn. Ìlo àǹkàrá àti léèsì fún aṣọ rírán ní ọ̀nà àràmàǹdà náà sì jẹ́kí iṣẹ́ yìí gbé pẹ́lí si. Oríṣiriṣiri ọ̀nà ni àwọn obìnrin ń gbà wé gèlè wọn báyìí dé bi wípé iṣẹ́ tí ẹlọ̀míràn ń ṣe kò ju ìyẹn (gèlè wíwé) lọ. Gbajúgbajà nínu àwọn aránṣọ ní orílẹ̀ èdè yìí ni: Frank Oshodi, Lánre Oshòdì, Ọmọniyì Makun, Josh Samuel, Mudiaga Enajemo, Bridget Awosika abbl.

Bí a bá fi Nàìjíríà wé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílè èdè adúláwọ̀, a o ri wípé o ti gbòòrò nínu iṣẹ́ yìí nígbàtí ó ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́ àti àrà tí ó ti fi aṣọ dá ní Paris ní odún 2000, ìyẹn Nigerian Fashion Show èyítí Legendary Gold ṣe agbátẹrù rẹ̀. Ní ti ṣe tìrẹ, kí n ṣe tèmi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-iṣẹ́ gẹ́gẹ́bí Sophisicate, Rose of Sharon, Vivid Imagination, Jimi King abbl ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn aṣọ káàkiri ayé, tíwọ́n sì ń wú ọ̀pọ̀lọpọ̀ lórí ní àgbáyé. Oríṣiríṣi ètò ìfaṣọhan ní orílẹ̀ Nàìjíríà àti ní àgbáyé ni orílẹ̀ èdè yìí ti ń gba oríyìn. Ndani, ìyẹn ọjà tí ìjọba kọ sí ìlú Ọba náà pẹ̀lú àwọn akitiyan tí orílẹ̀ èdè yìí ń ṣe lati ri wípé àwọn èèyàn lagbáyé rí iṣé àwon aránṣọ orílẹ̀ èdè yìí. Oríṣiriṣi magasínì ajẹmóge tí ń polówó aṣọ ni ó ti wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Lara wọn ni Flair West Africa, Genevieve, TW àti Arise.

Ní adúrú àwọn àgbéga yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà ní ó ṣì ń kọjú àwọn aránṣọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ṣé èèyàn ò kúkú lè rìn, kí orí rẹ̀ máà mì. Lára àwọn ìpèníjà yìí ni: àìsí èlò fún ṣíṣe aṣọ ìbílẹ̀ kò pọ̀ nílè, àísí owó fún àwọn ìwádìí tó lè mú ìyípadà àti ìdàgbàsókè wá fún iṣẹ́ yìí, wàhálà iná, aìdáàbòbò tó péye pèlú àwọn òfin tó lè de àwọn oníṣẹ́ aránṣọ pèlú ìṣòro àìlówó lọ́wọ́ lati ra àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé.

 

Àwọn Ìwé Atọ́kasí

Helen J.A. 2006. Patternmaking for Fashion Design. London: Pearson

Ltd.

John, G & Bryan, S. 1999. World Textiles: A Visual Guide To The Traditional

      Techniques. London: Thames & Hudson.

https://en.m.wikipedia.org/wiki/History_of_clothing_and_textiles March 3rd, 2016

https:// oldnaija.com/2015/07/01/fashion-in-early-nigeria/ May 5th, 2016.

 

.