ṢÓKÍ ÌRAN KỌKÀNLÁ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE ELEVENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Fẹ́mi àti Ṣọlá ṣe ayeye ìgbéyàwó ó dùn, tí ó tú lárinrin. Ọjọ́ kejì ìgbéyàwó, àwọn méjèjì lọ sí Jòhánẹsíbọ́ọ̀gì (Johannesburg) ní orílẹ̀ èdè Gúúsù Áfíríkà (South Africa) fún ìsinmi ọ̀sẹ̀ méjì. Ọjọ́ kejì tíwọ́n dé lati ibẹ̀ ni Fẹ́mi fún Ṣọlá ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Camry nítori okùnrin kankan kò tíì báa lòpò ríí gẹ́gẹ́bí ó ti sọ.

(Gbìyànjú kí o ka PRIZE FOR VIRGINITY)

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ náà niwọ́n lọ kí àwọn òbí Ṣọlá. Lẹ̀yìn tíwọn kí wọn tán, Fẹ́mi tún fún àwọn òbí Ṣọlá ni àpò ìwé kan tí ó kún fún ọ̀kẹ́ naira, ọ̀rá tí ó kún fún ọ̀pá mẹ́ẹ̀dógún léèsì àti wáìnì méjì. Ó fi dúpé fún àwọn òbí Ṣọlá pé òun “báa nílé”.

Lẹ́yìn èyí níwọ́n lọ sí ilé àwọn òbí Fẹ́mi. Fẹ́mi tún sọfún àwọn òbí rẹ̀ pé odindin lòun bá Ṣọlá, òun sì ti lọ dúpé fún àwọn òbí rẹ̀. Àwọn òbí Fẹ́mi ní ìyẹn kò tíì tó, pé ó yẹ kí Fẹ́mi kọ́kọ́ wá sọfún àwọn ná. Ní Ọjọ́bọ̀ (Thursday) ọ̀sẹ̀ náà, Fẹ́mi, Ṣọlá àti àwọn òbí Fẹ́mi jọ lọ sílé àwọn òbí Ṣọlá. Àwọn òbí rẹ̀ dúpé lọ́wọ́ àwọn òbí Ṣọlá. Olóyè, ìyẹn bàbá Fẹ́mi sì fi ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ Nissan Primera tá àwọn òbí Ṣọlá lọ́rẹ.

Lẹ́yìn tíwọ́n lọ tán, inú àwọn òbí àti àbúrò Ṣọlá dùn. Àwọn àbùró Ṣọlá fi tirẹ̀ ṣàríkọ́gbọ́n.