ṢÓKÍ ÌRAN KẸRÌNLÁ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE FOURTEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Kúnbi lọ kí Ṣọlá nílé ọkọ rẹ̀. Nígbà tíwọ́n jíròrò, Kúnbi sọpé Délé, lára àwọn ọ̀rẹ́kùnrin òun ti já òhun sìlẹ̀ lati fẹ́ ẹlòmíràn nítorí ó ká òun mọ́ Sínétò Lawal. Ó ní Kọ́lá Ajítòní, ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ míràn náà ti já òun jù sílẹ̀, nítorí mẹ́fà nínu ọ̀rẹ́ mẹ́jọ Kọ́lá ni o ti bá òun l’áṣepò. Ó ní òun àti Olóyè Mátànmí kò jọ ṣe mọ́ nítorí ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ dènà de òun pé kí òun dẹ̀yìn lẹ́yìn bàbá òun lẹ́yìn tí òun ti gba ìfọ́tí olóyì. Ṣọlá gbìyànjú àti fun ní’mọ̀ràn àmọ́ Kúnbi gé ọ̀rọ̀ mọ lẹ́nu.́

Ṣọlá sọfún Kúnbi pé ìlú òyìnbó lòun yòó bímọ sí nitorí Fẹ́mi fẹ́ lọ kàwé níbẹ̀. Kúnbi bèrè orúkọ ilé ìwé náà, Ṣọlá sì dáhùn pé London Business School ní University of London. Kúnbi fi orúkọ yìí sọ́wọ́ òsí, kò jẹ́ fi jẹun.

 

ṢÓKÍ ÌRAN KARÙNDÍNLÓGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE FIFTEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Ní ilé Bàbá Kúnbi, Ìyá Kúnbi ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ọrọ̀ ajé dé ni. Ó gba ilẹ̀ Faransé lọ sí Mẹ̀dínà àti Dùbàí lati lọ ra góòlù àti àwọn aṣọ olówó ńlá tí ó ń tà. Ó bá Kúnbi ra hot micro mini skirt àti àwọn nǹkan míràn wá fún Kúnbi. Bàbá Kúnbi ń ka ìwé ìròyìn níbẹ̀.

Lẹ́ẹ̀kan náà ni Kúnbi sọ pé òun fẹ́ lọ kàwé ní London. Nígbàtí bàbá rẹ̀ bèrè pé bàwo ló ṣe máa lọ sí London lọ kàwé nígbàtí kò tíì parí èyí tí ń kà lọ́wọ́ ní Nàìjíríà. Ìyá rẹ̀ ló dáhùn pé kí bàbá rẹ̀ jẹ́ kí ó máa lọ torí ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò dára. Ó ní òwó tí àwọn ti ná sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Nàìjíríà kò tó nǹkankan. Bàbá rẹ̀ náà gbà bẹ́ẹ̀.

Bí bàbá rẹ̀ ṣe fẹ́ máa ṣọ̀nà àti jẹ́kí ó bọ́ si ni Kúnbi ti ní School of Oriental and African Studies lòun fẹ́ lọ. Gbogbo ẹ̀ lòun àti ìyá rẹ tì dì lóri tẹlifòonu. Ó rí àyè sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Oṣù kẹsàn-an ló ye kí ó lọ, àmọ́ òṣu kẹfà ló sọpé òun yòó lọ. Ó lọ bá Fìkẹ́mi, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, kí ó tó lọ. Ó parọ́ fun pé ọ̀rẹ́ òun kan ló gba ọkọ mọ́ òun lọ́wọ́. Òun sì fẹ́ kí Fikẹ́mi ó mú òun lọ sí ọ̀dọ bàbá tí ó sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òun. Ìyẹn ní kí ó mú 100k (ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́run) kí òun tó mu lọ.

Ọjọ́ kejì ni ó mu lọ bá Abéṣùmùkọ. Kúnbi rojọ́ irọ́ fún bàbá yìí pé ọ̀rẹ́ òun ló gba ọkọ lọ́wọ́ òun. Ọkọ yìí sì fẹ́ mu lọ sí ìlú òyìnbo, òun kò sì fẹ́ kí lilọ ti ọrẹ̀ òun bọ́ si, Bákan náa ni òun fẹ́ kí ojú ọkọ oun yìí kúrò lára ọ̀rẹ́ òun sí ara òun. Bàbá bèrè #500 (ọgọ́run máàrun náírà) fún ìpèsè, Kúnbi sì fun ní ẹgbẹ̀rún méjì náírà. Ní ọjọ́ kẹta, bàbá fún Kúnbi ni àdó kan ti wọn fi aṣọ pupa we.

Bàbá ní òun yòó kọ ní ògèdè tí yòó má apè si. Ó ní kí ó gbe sí ibi tí atẹ́gùn kò ti ní fẹ́ si. Ó sọfun pé ọgbọ̀n-ọgbọ̀n ọjọ́ ni kí ó máa fún àdó náà lágbára pẹ̀lú ògèdè àti orúkọ Yòrúbá ọkùnrin náà. Ó fi le pé elòmíràn kò gbọdọ̀ rí àdọ́ náà tí ó bá ti pògèdè si, ó gbọdọ̀ ránti tutọ́ sí ọwọ́ àláfíà rẹ̀ kí ó tó pe ọfọ̀ náà torí atẹ́gùn kò gbọdọ̀ fẹ́ si. Bákan náà, kò gbọdọ̀ fọwọ́ rẹ̀ kan òkú.

Bàbá kọ ní ọfọ̀ náà, Kúnbi fún bàbá lówó, ó sì bá tirẹ̀ lọ.