ṢÓKÍ ÌRAN KẸ́SÀN-ÁN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE NINETH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Nínú ìran yìí ni ẹbí Fẹ́mi lọ mọ ẹbí Ṣọlá. Jíjẹ àti mímu wà. Kò ju àwọn èèyàn mẹ́rìnlá tí ó wà níbẹ̀, mẹ́fà lati ilé Fẹ́mi, mẹjọ ní lé Ṣọlá. Abẹnugan ìdilé Ọdúnowó, ìyẹn ìdílé àwọn Fẹ́mi, ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ó fi àníyàn wọn han pé ó wu Fẹ́mi kí ó wá já “òdòdó abẹ̀mí” ní ìdílé àwọn Ṣọlá. Bàbá Ṣọlá dáhùn pé bàbá tòun ni olorí ẹbí, òun tó bá sì ti sọ, labẹ ń gé. Olórí ẹbí pe Ṣọlá, ó sì bèrè lọwọ rẹ̀ bóyá ó wùú tọkantọkan lati fẹ́ Fẹ́mi. Ṣọlá ní pé òun ti ròó dáadáa, òun sì ti ṣe tán àti fẹ́ Fẹ́mi. Olórí ẹbí náà ni àwọn f’ara mọ. Oríṣiriṣi ẹ̀bun olówó iyebíye bíí àpótí aṣọ tókún fún aṣọ oríṣiriṣi pẹ̀lú oríṣiriṣi oúnjẹ.

Wọ́n bèrè lọ́wọ́ Fẹ́mi àti Ṣọlá ìgbà tí wọn ròpé ó dáa fún ìgbéyàwó náà, Fẹ́mi sì fèsì pé Dìsémbà làwọn ń fẹnu kò sí. Bàbá Ṣọlá ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ oṣú Dìsémba yòó dára nítori pọ̀npọ̀nsìnsì ọdún. Ìyá Ṣọlá ní àwọn yòó fi àkọsílẹ̀ àwọn ohun ìdána ránṣé sí ìdílé Odúnowó.

Bàyìí ni oníkálukú ń yọ̀. Kúnbi náà wà níbẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn àmọ kò fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.