ṢÓKÍ ÌRAN KẸWÀÁ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE TENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Fẹ́mi ń jẹun ní ilé óúnjẹ ìgbàlódé kan ni Kúnbi náà yà lọ ba níbẹ̀. Ó ṣebí ẹni pé òun kò mọ̀ pé Fẹ́mi wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó lọ jókòó ti Fẹ́mi níbi tábílì rẹ̀, ò sí ṣebí ẹni pé oúnjẹ́ lòun náà wá rà. Fẹ́mi san owó oúnjẹ rẹ̀, ni Kúnbí bá bèrè bóyá Olóyè, ìyẹn Bàbá Fẹ́mi gbà pé kí Fẹ́mi àti Kúnbi fẹ́ra. Ó ní àwọn òbí tòun kò lè gbà kí òun fẹ́ tálákà rárá. Ni Fẹ́mi bá sọ kùgbákùgbé ọ̀rọ̀ sí Kúnbi, ó sì bínú jade. Kúnbi tàka sí Fẹ́mi, ó sì lérí si.

Fẹ́mi dá nìkan ń sọ̀rọ̀ nínu ọkọ̀ rẹ̀ bí ó ṣe ń lọ lóri ìwà ìbájé àti áìlẹ́kọ̀ọ́ Kúnbi. Ó sì ń sọ si lọ́kàn pé Ṣọlá kán díbọ́ fún òun ni. Bí ó si ń sọ si lọ́kàn náà ni ó ń pe ara rẹ̀ padà pé ọmọ rere ni Ṣọlá. Ó sọfún Ṣọlá pé òun kò fẹ́ ọ̀rẹ́ òun àti Kúnbi nítorí ìwà burúkú tí ó ń wù. Ìyẹn fèsì pé òun yòó máa sún fun díẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó torípé òun ti sọfún Kúnbi pé òun ni yóò ṣe ọ̀rẹ́ ìyàwó. Yòó si fẹ́ rí bakan tí òun bá sọfun pé kí ó máà ṣe ìyọnu mọ́.

Ìpalẹ̀mọ́ ìgbéyàwó tí ń lọ ní pẹrẹu. Fẹ́mi sì ti gbèrò bakan náà pé òun yòó máa san owó ilé ìwé àwọn àbúrò Ṣọlá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.