ṢÓKÍ ÌRAN KẸJỌ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE EIGHTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Oṣù márùn-un lókùn fún Ṣọlá lati lọ fún àgùnbánirọ̀. Ó wu Fẹ́mi kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó kí Ṣọlá tó lọ, nítorí Fẹ́mi kò tíì ṣi láṣọ wò lati ìgbà tí wọ́n ti ń ṣe wọlé wọ̀de. Ṣọlá ni ọkọ òun nìkan ló lè gba ìbálé òun. Ṣọlá náà gbà, wọ́n sì jọ lọ sí ilé àwọn òbí Fẹ́mi lati sọ̀rọ̀ lóri bí wọ́n ṣe jọ máa lọ bá àwọn òbí Ṣọlá fún mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́.

Ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó Fẹ́mi àti Ṣọlá ni àwọn òbí Fẹ́mi ń sọ lọ́wọ́ nínu yàrá ni Fẹ́mi dé bá wọn. Ó sọfún wọn pé ìdí tí òun fi wá sí ọ̀dọ̀ wọn náà nìyẹn, àtipé Ṣọlá wà ní pálọ̀. Wọn sọ fun pé kí ó jẹ́kí Ṣọlá wọ inú yàrá, torípé òun náà ti di ọmọ àwọn. Báyìí ni Ṣọlá ti wọlé kíwọn. Fẹ́mi sọpé oṣù ọpẹ làwọn fẹ́ ṣé, àmọ́ Ṣọlá ní òun ní lati gbọ́ ọjọ́ tí yòó rọrùn fún àwọn òbí òun.

Nígbàtí Ṣọlá padà sílé, ó pe Kúnbi lóri fóònù, ó sì fi tóo léti pé àwọn kò ní pé ṣe mọ̀-mí-n-mọ̀-ọ́. Bákan náà  nipé àwọn kò ní pẹ́ ṣe ìgbéyàwó, Ṣọlá lòun fẹ́ kí Kúnbí ó ṣe ọ̀rẹ́ ìyàwó (bridesmaid) lọ́jọ́ náà. Kúnbi gbà lati ṣe bẹ́ẹ̀.