ṢÓKÍ ÌRAN KEJE ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE SEVENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

‘Tèmi nìkan’ ni orúkọ tí Fẹ́mi máa ń pe Ṣọlá lati ìgbà tíwọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́ ara wọn. Fẹ́mi mú Ṣọlá lọ sí ilé rẹ̀. Ẹnu ya Ṣọlá bí Làmídì, aṣọ́géètì ilé Fẹ́mi ṣe ń bá Fẹ́mi sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọwò. Ilé náà tóbi, ó sì lẹ́wà púpọ̀. Ọkọ̀ mẹta ni ó sì wà níwájú ìta ilé náà. Ẹnu ya Ṣọ́lá fún àwọn nǹkan mèremère tí ó rí nínu ilé náà. Ó fihàn gedegbe pé olówó ni ó ní. Nígbà tí Fẹ́mi fi àwòrán àwọn òbí rẹ̀ han Ṣọlá ni Ṣọlá tó ri pé ọmọ gbajúmọ̀, Olóyè Ọlápeléke ni Fẹ́mi. Fẹ́mi sọfun pé Adéfẹ́mi Johnson Ọlápeléke ni orúkọ òun ní kíkún. Òun sì mọ̀ọ́mọ̀ máa fihàn sí Ṣọlá ni, nítorí òun fẹ́ mọ̀ bóyá yóò nifẹ òun. Ṣọlá fi ye pé díẹ̀ ni towó, ìfẹ́ ló ṣe kókó. Ṣọlá gbàá nímọ̀ràn pé kí o máa ṣiṣé tirẹ̀, kí ó máà si gbójúlé owó àwọn òbí rẹ̀ nìkan. Ìyẹn sì fi ye pé òun ní iṣẹ́ òun lọ́wọ́, kódà òun lòun kọ́ ilé òun, bàbá òun kàn ra ilẹ̀ lásán ni.

Ó gbe padà lọ sí ilé ìwé nígbàtí ó yá. Ó fun lowó, Ṣọlá dúpé lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fẹnu kòó lẹ́nu. À ṣé Kúnbi ń wo Ṣọlá bí ó ti ń jáde nínu ọkọ̀, ó rópè ọkùnrin míràn ni. Ṣọlá fiye pé Fẹ́mi náà ni, kìí ṣe ẹlòmíràn. Kúnbi ròpé dírébà lásán ni Fẹ́mi. Ṣọlá ni ó ṣẹ̀ẹ̀ṣè fiye pé ọmọ kan ṣoṣo tí gbajúmọ̀ Olóyè Ọlápeléke ni. Ó ká Kúnbi lára gan, ó sì kabamọ̀ gbogbo ìwọ̀sí tí ó ti fi Fẹ́mi ṣe. Lẹ́yìn náà, ó gbíyànju lati fa ojú Fẹ́mi mọ́ra ṣùgbọ́n ìyẹn kò f’ojú sílẹ̀ fun.

Lẹ́yìn ìdánwò àṣekágbà, Ṣọlá yege, ó sí múra lati di àgùnbánirọ̀ ṣùgbọ́n Kúnbi fìdí rẹmi, àgùnbánirọ̀ kò ṣééṣe fun.