ṢÓKÍ ÌRAN KẸRIN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE FOURTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Kedegbe ni ati rí ìwà Ṣọlá àti Kúnbi pẹ̀lú ìdílé tí wọ́n ti wá. Bákan náà ni a ti mọ ẹni tí Fẹ́mi ń ṣe. Ẹ máa sì gbàgbé pé inú yàrà kan ni Ṣọlá àti Kúnbi ń gbé. Kúnbi ń ka ìmọ̀ Lìngúíísíkì nígbàtí Ṣọlá ń ká ìmọ Yorùbá.

Nínú ìran yìí, Fẹ́mi lọ kí Ṣọlá ní ìbùgbé àwọn obìnrin (girls’ hostel). Kúnbi ni ó bá nilé, ìyẹn kò sí ṣe bí ẹni tí ó mọ̀ọ́ rárá. Ò wọ́ nílẹ̀, ó sì sọfun pé ó lé dúró de Ṣọlá tí kò bá ní iṣẹ́ ṣe. Fẹ́mi ní kó bá òun jíṣé fún Ṣọlá pé òun bèrè rẹ̀, kò fi ìwà Kúnbi ṣe ìbínú rárá.

Kúnbi jáde lọ, ó sì wọlé lóru. Nígbàtí Ṣọlá bèrè ibi tó gbàlọ lówúrọ̀ ọjọ́ kejì, èèbú ni ó fi fèsì. Ó sì sọfun pé Fẹ́mi bèrè rẹ̀. Ó sọfun pé kí ó máà fẹ́ ọkùnrìn bíi Fẹ́mi, nítorí pé kò lówó lọ́wọ́. Ó ní òun kò lè fẹ́ ọkùnrin tí kò lówó lọ́wọ́. Kúnbí fèsì pé Fẹ́mi ti níyàwó tirẹ̀, bí kìí bá ṣe bẹ́è ni, òun yòó fẹ tí ó bá níwà gidi, kò báì tálákà ju èkúté ṣọ́ọ̀ṣì. Kúnbi kọrin Olówó mó ba lọ, ó dágbére, ó sì jáde lọ. Ibi tí Ṣọlá ti ń kàwé ni Fẹ́mi kan ilẹ̀kùn.

Ṣọlá ní kó máà bínú pé òun kò sí nílé nígbàtí ó wá. Ó jókò lórí àgà, Ṣọlá lọ ba ra ọtí ẹlẹ́rindòdò nísàlẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó ya Fẹ́mi lẹ́nu pé èèyàn bí Ṣọlá àti Kúnbi lè jọ máa gbé papọ̀ nítori ìwà wọn tí ó yàtọ̀ gedegbe. Ṣé fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí, kí n sọ irú èèyàn tí o jé ni Yorùbá sọ. Ṣọlá fèsì pé mòwàfóníwà ló ń jẹ́ ọ̀rẹ́jọ̀rẹ́ lọ́dọ̀ tohun. Wọ́n takùrọ̀sọ̀ díẹ̀, kò pé tí Fẹ́mi lọ.