ṢÓKÍ ÌRAN KAÀRÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE FIFTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Ìfẹ́ àárin Fẹ́mi àti Ṣadé ń pee léke si lójoojúmọ́, àmọ́ Fẹ́mi kò tíì dẹnu ìfẹ́ kọ Ṣọlá. Ṣọlá náà kò sì ṣẹtán àti fẹ́ẹ nitorí pé ó rò pé ó ti ní ìyàwó. Olóyè Ọdúnowó Ọlápeléke ni bàbá Fẹ́mi, Ṣadé sì ni orúkọ ìyá rẹ̀. Àpèjuwe ilé wọn fihàn pé ilé ọlọ́lá nilé wọn.

Nínu ìran yìi, à ri pé Fẹ́mi ti níyàwó tẹ́lẹ́ bí ọdún máàrún sẹ́yìn, Títílayò lorúkọ rẹ̀. Nígbàtí ó ń rọbí lọ́wọ́ ni ó kú tọmọtọmọ.. Lati ìgbà náà ni Fẹ́mi kò ti fẹ́ ìyàwọ́ míràn mọ́. Ìdí nìyíí tí àwọn òbí rẹ̀ fi pèé lati fun ní ìmọ̀ràn pé ó ye kí ó ti fẹ́ ìyàwó míràn lẹ́yìn ikú ìyàwó rẹ̀. Wọ́n ní àwọn bùkátà sí ọmọ-ọmọ nítorí Fẹ́mi nìkan làwọn bí.

Fẹ́mi fèsì pé lòótọ́ lòun ti pinu pé òun kò ní fẹ́ obìnrin míràn mọ́ lẹ́yìn ikú Títílayọ̀ nítorí òun rò pé òun kò lè rí irú rẹ̀ mọ́. Àti pé owó lọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ń wá. Ó ní òun ti pàdé Ṣọlá, òun kò sì jẹ́ kí ó mọ́ pé ilé ọlówó lòun ti wá. Ó ní àmọ́ òun kò tíì dẹnu ìfẹ́ kọọ́, òun kò sì ní pé ṣe bẹ́ẹ̀. Inú àwọn òbí rẹ̀ dùn-uǹ.

Ní ọjọ́ Sátidé kan ni Fẹ́mi lọ kí Ṣọlá, Kúnbi si ti jade lọ gẹ́gẹ́bí ìṣe rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Fẹ́mi sọfún Ṣọlá pé kí àwọn jọ jáde ṣùgbọ́n Ṣọlá kọ̀ jálẹ̀ nítorí pé kò fẹ́ joyè gbọkọgbọkọ. Ó ní yòó ba orúkọ òun jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni òun náà kò lè gba irú rẹ̀. Ìgbá yìí ni Fẹ́mi tó ó sọfun pé òun kò ní ìyàwó. Ó ní bí ó bá tẹ̀lé òun jáde, òun yòó sọ èyí tókù fun. Ìgbàyìí ni Ṣọlá gbà pé kí àwọn jọ jade lọ wo afihan sinimá Taxi Driver tí Adé Love ṣe.