ṢÓKÍ ÌRAN KẸRÌNDÍNLÓGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE SIXTEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Ó kun ọ̀la kí Fẹ́mi lọ ìlú Òyìnbọ́, ìwé ìyọ̀nda Ṣọlá kò bọ́si ládúrú gbogbo ipá tí bàbá Fẹ́mi sà. Inú Ṣọlá kò dùn rárá pé ọkọ òun ti ń lọ. Fẹ́mi ṣèlérí fun pé ojoojúmọ́ lòun yòó máa pèé, àwọn yòó sí̀ máa rí ra lórí SYPE. Ṣọlá ní kò lè dàbí. Fẹ́mi ṣá ń da lẹ́kún títí wọ́n fi sùn. Bí ago méjì òru, Ṣọlá ṣàdédé kígbe látojú orun. Ó lá àlá pé ibi tí òun àti Fẹ́mi ti ń sáré pèlú ìdùnú ni ìjì líle kan gbé adé ọwọ́ òun lọ. Òun kò si rí adé àti Fẹ́mi, ní oun fi jí bí òun ti ń kígbe lójú àlá. Fẹ́mi ní kò sí nǹkankan, torí nǹkan tí Ṣọlá ń rò ló fàá.

Ní ọjọ́ kejì, àti lọ London Fẹ́mi ti yá, Ṣọlá àti àwọn òbí rẹ̀ sìn-ín dé pápákó òfúrufú.

ṢÓKÍ ÌRAN KẸTÀDÍNLÓGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE SEVENTEETH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Gbogbo nǹkan ń lọ létòlétò. Fẹ́mi á máa pe Ṣọlá lójoojúmọ́. Ṣọlá ti bẹ̀rẹ̀ àgùnbánirọ rẹ̀. Lẹ́yìn bí oṣù méjì, Fẹ́mi ń jẹun nílé oúnjẹ lọ́jọ́ kan, Kúnbi lọ ba níbẹ̀. Ẹnu ya Fẹ́mi pé Kúnbi wa ní London, ìyẹn sì sọfun pe School of Oriental and African Studies lòun wà. Fẹ́mi kò sọ ibi tí ó ń gbé fun àmó Kúnbi ṣe ìwádìí ibi ti ó ń gbé. Ó ṣa ògùn tíwọ́n gbé fun, ó wọ ìwọ̀kuwọ̀ lọ ba nílé.

Ara Fẹ́mi ṣe gìrì bó ṣe ri Kúnbi, ògùn ìfẹ́ náà sì mu. Kò tilẹ̀ pe Ṣọlá mọ́. Ṣọlá ń ronú nílé, ìfúnpá sì ń ga. Kíà, àwọn òbí ọkọ rẹ̀ ti mu sọ́dọ̀. Wọn fií lọ́kàn balè pé àwọn yòó wádìí. Ìyá Ṣọlá náà sọpé iṣẹ́ ló fàá.

Kúnbi lóyún fún Fẹ́mi, inú Fẹ́mi sì dùn gan ni torí ògùn ṣì ń ṣiṣẹ́ lára rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *