Ìyàtọ̀ Láàrín Télò Àti Dìsáínà

Láti ọwọ́ Hassan Abdulbaqi

 

Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, awuyewuye máa ń sábà maá n wà láàrín “télo (tailor)” ìyẹn iṣé aránṣọ ní èdè gẹ̀ẹ́sì àti “dìsáínà (fashion designer)” Ìbéèrè sábà máa ń wáyé lóri bóyá ìyàtọ wà láàrín àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn kan ní ìgbàgbọ́ pé ẹyọ̀kán gbé pẹ́lí ju èkejì lọ, òmíràn sì ròpé akọ àti ìmúni lórí yá lásán ni ó wà fún nítorí télò ni àwọn èèyàn ti ń pe àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ yìí lati ọjọ́ pípẹ́, à́mọ́ tí “fashion designer” dé pẹ̀lú ìtúnmọ ìgbàlódé àti ọ̀làjú. Àwọn míràn tilẹ̀ gbàgbọ́ pé kò sí ìyàtọ̀ kankan láàrín wọn. Ẹlọ̀míràn mọ̀ pé ìyàtọ̀ wà láàrín wọn ṣùgbọ́n kò mọ ìyàtọ̀ náà.

Ìwádí nínú èdè gẹ̀ẹ́sì gangan fihàn pé ìyàtò ń bẹ láàrín wọn. Gẹ́gẹ́bí ó ti rí nínu Oxford Advanced Learners’’ Dictionary (àtúnṣe elékẹjọ), télọ̀ ni “ẹni tí ó máa ń rán aṣọ ọkùnrin sílẹ̀ ní oríṣiríṣi ìwọ̀n lati fi lè jẹ́ kí ó bá gbogbo awọn ọkùnrin oníbárà rẹ̀ mu rẹ́gí, “eni tí o máa ń rán aṣọ obìnrin sílẹ̀ bákan náà ni àwọn olóyìnbọ́ ń pè ní “seamstress”. Ìyẹn ni pé, bí ìjàpá àti yáníbọ ṣẹ wà náà ni tailor àti seamstress wà. Ẹni tí ń gbèrò bí aṣọ yóò ṣe ri pẹ̀lú yíya bátánì fún wọn ni “fashion designer” tàbí “couturier”.

Ìyàtọ̀ gbòógì tí ń bẹ láàrin wọn náà ni pé, dìsáina (fashion designer) máa ń ya bátánì bí aṣọ yòó ṣe rí kí wọn to dáwọ́ lórí wọn. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé kí aṣọ ba lè di wíwọ̀ ni àníyàn àwọn méjèèjì, kò sí tàbí sùgbọ́n wípé iṣé “fashion designer” gbé pẹ́lí ju ti télò lọ.

Ìwadi siwaju si lọdọ awọn ti n ṣe iṣẹ yii tún làwá lọyẹ nipa iṣẹ yii ni ibamu pẹlu bi nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Dìsáínà ni igi lẹ́yìn ọgbà ọ̀pòlopọ̀ aṣọ mútìẹ (ready made) olọkan ò jọ̀kan tí à ń rí. Wọ́n máa ń ṣe ìwádìí, ìrokàn àti bátánì afipilẹ̀ fún àwọn oníbárà wọn. Ìyẹn ni pẹ́, kì í ṣe ìgbà tí dìsáínà bá rí oníbárà ni iṣẹ rẹ tó máa bẹ̀rẹ̀. Ìlo ẹ̀rọ kòmpúta àti iṣírò oríṣiriṣi pẹ̀lú ara iṣẹ dìsáínà. Ìyẹn ni pé, ìwé kíkà kún nǹkan ti a fi n di dìsáínà nígbàtí kò rí bẹ́ẹ̀ fún télò.

Ní bí ọdún 1980 lọ sí ìsàlẹ̀, kò sí ìyàtọ̀ láàrín àwọn aránṣọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Ìfọ̀rọ̀wérò tí a ṣe pẹ̀lú àwọn télò àgbà fihàn pé gbogbo iṣẹ́ aránṣọ ni télọ̀ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ dé ibi rírán pátá àti kọ́mú, eléyìí tó jẹ́ pẹ́ ìsọ mútìẹ nìkan ni a ti lè báa pàdé ní òde òní. Eléyìí fi ojú hàn níbi orúkọ àwọn gbajúgbajà aránṣọ bí Télọ̀ Ògúndẹ̀rọ̀, Tẹ́lọ̀ Fágbohùn, Télọ̀ Lai Olumegbon àti Télọ̀ Ìdòwú. Ní adúrú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn télọ̀ yìí lọ kọ́ iṣẹ́ wọn ní Òkè Ọba, ìyẹn kò yí orúkọ wọn padà sí dìsáínà.

Ìdí nìyìí tí a fì dá àbá “aránṣọ” gẹ́gẹ́ bí orúkọ fún télò okùnrin àti obinrin ti wọn ṣiṣẹ télò, tí a sì dábá “aránṣọ ìgbàlódé” tàbí “dìsáínà” fún “fashion designer/couturier” nínu iṣẹ́ yìi. “Aṣaralóge”” tí kò bá sunmọ ju fun ni awọn sinima agbelewo Yorùbá ti fún orúkọ awọn ti maa n tọ́jú-tọ ete fún awọn òṣèré. Ọ̀rọ̀ míràn tí a kò bá tún lò ni “aranṣọ nlá”” nigbati a sọpe ise re gbe peli ju ti telọ lọ gẹgẹbi a ti ri nínu:

Oníṣòwò: ẹni tí ó ń ṣòwò, Oníṣòwò ńlá: ẹni tí òwò ti rẹ̀ mú owó wolé ju ti oníṣòwò lásán lọ.

Ṣùgbọ́n a ti sọ síwájù tẹ́lẹ̀ pé bàtánì gangan ni iṣẹ́ kan gbòógì tí ó pọn dandan kí dìsáínà ó rán aṣọ, kí a sì pè é ni “aranṣọ nla” kò ní gbé ìtunmọ̀ tí a fẹ́ gbé jade. Bakan náà nipé, ọ̀rọ̀ yị́í lu pọ́nna nítorí ó tún ní ìtunmọ̀ “ẹni tí ó ń rán aṣọ tí ó tob́i”.

Ẹlómíràn ní ìgbàgbọ́ pé kò pọn dandan kí Yoruba náà ní orúkọ fun ṣugbọn kilode tí a fi ni orukọ ọtọ fún awọn mọ́là tí n gbe ẹrọ kọ ejika iyen awọn ti ejika ni ṣọọbu? Ní òkúrú ìgbà tí iyatọ tí o fi oju han ti wa laarin wọn, dandan ni ki orukọ wọn jẹ ọtọtọ ki a maa ba gbe ọmọ Ọbà fún Òṣun. Kí ni èrò tìrẹ?

 

Àtọ́kasi Ìwádìí

https:// oldnaija.com/2015/07/01/fashion-in-early-nigeria/ May 5th, 2016.

Bákan náà ni mo dúpẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ Alàgbà Yusuf Alao, olórí ẹgbẹ́ télọ̀ ní ìlú Ìsẹ́yìn tí wọ́n bá ọ̀rẹ́ mi, Adélékè Abdulateef ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Bàbá, àgbà yín kò ní tán nílẹ̀ ooo. Àmín.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *