ṢÓKÍ ÌRAN KÍNÍ ÌWÉ WAẸẸKI ÀTI NẸ́KÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBIGBÉ MORÓNMÚBỌ̀ MARTINA KỌ

Lati ọwọ́ Hassan Abdulbaqi

 

Kúnbi àti Ṣọlá ń fí ọ̀rọ̀ wérò ní ọgbà ilé-ẹ̀kọ́ yunifásítì Àfọ̀ǹjá. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn fihàn pé ọ̀rẹ niwọ́n. Ó sì fihàn bakan náà pé Kúnbi kò mójú tó ẹ̀kọ́ rẹ̀, bákan náà ni ó máa ń sábà tẹ̀lé oríṣiríṣi ọkùnrin pẹ̀lú pé ilé olówó ni ó ti jáde. Èyí yàtọ̀ gedegbe sí ìwà Ṣọlá tí òbí rẹ̀ kò lówó lọ́wọ́ ṣugbọn ó jé ọmọ tó gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nínu ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn, Ṣọlá ń gba Kúnbi ní ìmọ̀ràn kí ó kọjú mọ́ ìwé rẹ̀, kí ó sì yéé tẹ̀lè ọkùnrin káàkiri. Kúnbi sì ń dáa lóhùn pé òun gbọdọ̀ jayé orí òun. Ibi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lọ lọ́wọ́ ni arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fẹ́mi dé báwọn.

(Gbìyànjú kí o ka BÍ ÌDÁNWÒ YORÙBÁ ÀṢEKAGBÁ (WAEC/NECO) RẸ YÒÓ ṢE RÍ)

Fẹ́mi kí àwọn méjèèjì ṣùgbọ́n Ṣọlá nìkan ló dáhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Fẹ́mi bèrè ọ̀nà gbọ̀ngàn eré idárayá lọ́wọ́ wọn àmọ́ Ṣọlá nìkan ló fésì, tí ó sì mú arákùnrin yìí dẹ́bẹ̀ pèlú pé ó sì ni iṣé ní ilẹ́ ìwé lẹ́yìn wákàtí kan àbọ̀, kò sì tíì jẹun. Ọkùnrin yìí fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́bí Fẹ́mi Johnson, Ṣọlá náà sì fèsì pé Ṣoláyídé Tèmíladé Ẹgbẹ́dá lorúkọ tòun.

Lẹ́yìn tí Ṣọlá mú Fẹ́mi dé bè tán-án, Fẹ́mi bẹ Ṣọlá pé kí ó dúró de oun, pé òun kàn fẹ́ sáré fún èèyàn ní nǹkan. Lẹ́yìn tí ó ṣe tán, ó bẹ Ṣọlá pé kí ó tẹ̀lé òun lọ jẹun ní ilé oúnjẹ. Ilé oúnjẹ ńlá tí àyíká rẹ̀ tutu niwọ́n lọ. Ṣọlá ka jíjẹ oúnjẹ ní irú ibẹ̀ sí ìfowóṣòfò nígbàtí àwọn ilé oúnjẹ òmíran wà tí wọn ti ń jẹ oúnjẹ kan náà ní owó pọ́kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí èèyàn fi owó náà dáná ní lé ara rẹ̀. Orí Fẹ́mi wú pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ̀ tí ń jábọ́ lẹ́nú Kúnbi.

Nígbà tí ó yá, Ṣọlá ri pé òun ti fẹ́rẹ̀ pẹ́ fún iṣẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ máa lọ. Fẹ́mi ní ó wu òhun àti rí Ṣọlá lẹ́ẹ̀kan si, Ṣọlá sì dáhùn pé kò sí nínu ìwà òun àti máa jáde pẹ̀lú eni tí ó ti níyàwó. Lẹ́yìn tí wọ́n fàálọ, fàábọ̀, wọ́n gba nọ́mbà ara wọn. Fẹ́mi sin Ṣọlá padà sí yàrá ìkàwé, wọ́n sì túká.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *