Ìdàgbàsókè Nínu Aṣọ Wíwọ̀ Àti Iṣẹ́ Ìránṣọ Lati Ìṣẹ̀wá
Lati o̩wó̩ Hassan Abdulbaqi

Dandan ni kí ọ̀rọ̀ aṣọ jẹyọ nínu iṣẹ aṣọ rírán gẹ́gẹ́bí ó ti di òranyàn kí ọ̀rọ ẹ̀wà jẹyọ nínu ìpèsè móín-móín nítorípe iṣẹ́ aránṣọ jẹmọ́ gbogbo ìgbèrò, ìpèsè àti ìyabátánì tí a fi ń jẹ́ kí aṣọ di wíwọ̀. Aṣọ ni gbogbo iṣẹ́ aṣọ rírán dá lé lórí. Kódà, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe máa fihàn nínu iṣẹ́ yìí, ìdàgbàsókè aṣọ àti iṣẹ́ aṣọ rírán wọ inú ara wọn ni.
Láì sí àní àní, aṣọ wíwọ̀ jẹ́ àṣà tí ó kárí ayé, tí ó sì jẹ́ ara àwọn àbùdá tí ó jẹ́ kí ọmọ ènìyàn yàtọ̀ sí ẹranko. Ẹ̀rí fihàn lati inú Bíbélì (King James Version, Jẹ́nẹ́síìsì 3:7) àti Kùránì (The Noble Qur’an Translation, Suratul Arafu:22) wípé ní àti ayé bàbá ńlá wa Ádàmọ́ ní bíbo ìhòhò ara wa ti bẹ̀rẹ̀. Bíbélì sọpé “Ojú àwọn méjèèjì (ìyẹn Ádámù àti Ééfà) sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọ́n wà ní ìhòhò; wón sì gán ewé ọpọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì dá ìbàntẹ́ fún ara wọn.” (King James Version, Jẹ́nẹ́síìsì3:7). Nínu Kùránì, Al̀ahù ràbí sọpé: Ó (Èṣù) sì mú àwọn méjèèjì ṣìnà pẹ̀lú ìtànjẹ. Nígbàtí àwọn méjèèjì tọ́ igi náà wò, èyí tí ó pa mọ́ fun wọn sì hàn sí wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní fi nínu ewé ọgbà ìdẹ̀ra náà bo ara wọn.”(The Noble Qur’an Translation, Suratu Arafu:22).
Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, pàápàá jùlọ nípa ìmọ̀ nínu ìdàgbàsókè, àṣà àti ìgbàgbọ́ fiyé wa pé ara eranko àti ewé ni àwọn èèyàn máa ń lò gẹ́gẹ́bí ìbora lati fi dènà de òtútù, ooru àti òjò pàápàá jùlọ tí omọnìyàn bá kó lọ sí àdúgbọ̀ tuntun ní ìwásẹ̀. Lati ìgbà pípẹ́, títí di ìsìnyí ni onírúrú ọ̀nà tí à ń gbà ń ṣe aṣọ ti ń gùnkè, tí ó sì ń gbòòrò pẹ̀lú. Ẹ̀kọ́ nípa ìbátan ẹ̀jẹ̀ mú ẹ̀rí wá pé kòkòrò tí o máa ń gbé nínu aṣọ ti wà lati ìgbà pípẹ́, èyí náà fihàn pé láti ìbẹ̀rẹ̀ ìsẹ̀mí ọmọnìyàn ni aṣọ wíwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn litiréṣọ̀ àpilẹ̀kọ, àwòrán ayé àtijọ́, àṣà ìsìnkú àti ewì àbáláyé fihàn bakan náà pé aṣọ wíwò ti wà láti ìgbà tí ayé ti bẹ̀rẹ̀. Bí ẹgbẹ̀rún ogójì ọdún sẹ́yìn ní àkọsílẹ̀ wípé abẹ́rẹ́, ìyẹn ara ohun èlò fún aṣọ rírán, ti wà tí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ fún rírán aṣọ. Gbogbo eyi n fi rinlẹ̀ pé àti ayébáyé ni aṣọ ti wà.
Ìyàtò ńlá dé bá aṣọ wíwọ̀ ni sẹ́ńtúrì kejìlá àtí kẹtàlá nítorí ìgbéga tí ó débá iṣẹ́ aṣọ ṣíṣe lapapọ̀. Ní sẹ́ńtúrì kẹtàlá ni ati rí àgbéga nínu iṣẹ́ àdìrẹ̀ àti òwú ṣíṣe, èyí tó jẹ́ èlò tó wúlò jù fún áṣọ ní ìgbà náà. Ọ̀pọ̀lọpò ló sọ iṣẹ́ àdirẹ àtí òwú ṣíṣe di iṣẹ́ òòjọ́ wọn.
Àwọn onítàn nípa àṣà àti aṣọ fi ẹnu kò pé láàrín sẹnturi kẹ̣rinla ni oge ojúlówó ti bẹ̀rẹ̀. Lati ìgbà yíí ni ayé ti gba aṣọ wíwọ̀ lágbàtán. Aṣọ́ kúrọ̀ ní nǹkan tí a kàn wọ̀ lásán fún bíbọ̀ àṣírí lọ sí ohùn tí a fi ń fi èho inú hàn, ẹ̀ṣọ́ àti àmì ìdánimọ̀ tí ó ń fi àṣà, ipò láwùjọ àti iṣẹ́ hàn (John àti Bryan 1999:10-11). Àsìkò yìí ni aṣọ wíwọ̀ fún ṣíṣe ìbánisọ̀rọ̀ gbajúmọ̀. Aṣọ ọkùnrin àti ti obìnrin sábà máa ń fẹ̀. Ìyàtọ̀ púpọ̀ ló sì wà láàrín aṣọ bọ̀rọ̀kìní àti tálákà nítorí àwọn bọ̀rọ̀kìní máa ń fẹ́ fi dúkìa wọn hàn pẹ̀lú aṣọ wíwọ̀.
Àwọn onímọ̀ nípa àṣà àti ìtàn fi ẹnu kò pé àárín sẹ́ńtúrì kẹrinla ni nǹkan tí a lè pè ní oge aṣọ wíwọ̀ bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yíí gan-an ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ asọ tí ó bá wọn lára mu nitori iṣẹ́ aṣọ rírán ṣẹ̀ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, àsìkò yíí gan-an náà níwọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lo bọ́tìnì. Aṣọ àríìrí gbajúgbajà ní sẹnturi karunla, àsìkò yíí ni àṣà ìfi àrà olódòdó sí aṣọ bẹ̀rẹ̀, tí ó sì kárí ìlú Ọba nígbà náà. Ní Mughal India láàrín sẹ́ńtúrì kẹfàlá títí dé senturi kẹjọla ni a ti rí ilé iṣẹ́ ńlá tí ó gbòrò jùlọ ní ìdí aṣọ ṣíṣe àti aṣọ títà.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ sẹ́ńtúrì ogún, ilé ẹ̀kọ́ gíga gẹ́gẹ́bí DC Davis gbé Division of Textile and Clothing kalẹ̀, Ifáfitì Nebraska-Loncoln náà dá ẹ̀ka Aṣọ àti Àrà níbití àwọn akékọ̀ọ́ ti ń gba oyè degree. Bákan náà ni ti Ifáfitì Lowa tí ó dá Eka Aṣọ kalẹ̀ sí ifáfitì. Bayìí ni o ṣe ń ga si títí di sẹ́ńtúrì tí a wà yìí. Àsìkò yìí náà ni ẹ̀rọ ìranṣọ dé tí ó sì kó ìrọ̀rùn bá ẹyẹ àti omi awọn aranṣọ àti oníbárà wọn.
Àjọ tí ń bójú tó aṣọ ṣiṣe àti rírán ní àgbàyé gẹ́gẹ́bí a ti rí ní United Nations Commodity Trade Statistics Database fihàn pé aṣọ tí ń jade sún kúrọ̀ níbi díẹ̀ sí púpọ̀ nítorí aṣọ tuntun ń jade ní yanturu ní àgbáńlá ayé. Báyìí ni aṣọ àti aṣọ rírán ṣe tàn kárí ayé títí di sẹ́ńtúrì tí a wà yìí.
Ò̩rò̩ nipa ìdàgbàsókè as̩o̩ rírán ní orílè̩ èdè Nàìjíríà yòó wáyé ló̩la lágbára Àllahù Ràbí.