ṢÓKÍ ÌRAN KEJÌDÍNLÓGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE EIGHTEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Ṣọlá bí ìbejì, okùnrin kan obìnrin kan sílé ìwòsàn. Ṣọlá ń sunkún pé òun kò tìí rí Fẹ́mi bá sọ̀rọ̀. Wọ́n gbìyànjú àti pé Fẹ́mi lati sọfun pé aya rẹ̀ bímọ, wọn kò ri pè. Ọwọ́ Kúnbi ni lẹ̀tá Bàbá Fẹ́mi bọ́ sí, ìyẹn sì yá là í jẹ́ kí Fẹ́mi mọ̀. Lọ́jọ́ ìkómo, Olóyè ló náwó, wọ́n sì gbìyànjú àti jẹ́kí inú Ṣọlá dùn.

 

ṢÓKÍ ÌRAN KỌKÀNDÍNLÓGÚN ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE NINETEENTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Kúnbi ti ti Fẹ́mi sí ìnákúnà dé bi pé owó ọwọ́ rẹ̀ tán. Ó ti di ẹnití ń yá wó lọwọ àwọn ọ̀rẹ́ kiri. Síbẹ̀, eléyìí kò tẹ́ Kúnbi lọ́rùn. Ó ní òun ṣì nílò àti ra àwọn nǹkan ọmọ si. Ó ní kí ó pe bàbá rẹ̀ tí kò bá sí owó lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́, ìyẹn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹnu ya bàbá rẹ̀ nígbà tí ó rí ipe Fẹ́mi tí nọ́mbà rẹ̀ kò lọ lati ọjọ́ yìí, à ṣé ó ti pàrọ̀ nọ́mbá ni. Kíá ló gé ọ̀rọ̀ mọ́ bàbá rẹ̀ lẹ́nu bí ìyẹn ti ń bèrè àlááfíà rẹ̀. Ó ní kí bàbá yá òun ni 100pounds. Ìyẹn bèrè pé kí ló fẹ́ fi ṣe., ó ní òun fẹ́ fi ra nǹkan ọmọ torí ìyàwó òun lóyún. Ẹnu ya bàbá rẹ̀, ó bèrè ibi tí ó fẹ́ fi Ṣọlá, ìyàwọ́ tó bí ìbejì fun. Ó ní wàhàlá ti Ṣọlá nìyẹn. Bí bàbá rẹ̀ ti fẹ́ máa bawí ni Kúnbi ti ṣẹ́jú si pé kó pa fòónù mọ́ bàbá rẹ̀ lẹ́nu, òun náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Bàbá Fẹ́mi múra àti lọ London lọ́sè tó tẹ̀le nígbà tí eléyìí ṣẹlẹ̀ tán. Ó sọfún ìyàwó rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò jẹ́kí Ṣọlá gbọ́ nǹkankan. Kí bàbá tó dé London, Kúnbi ti bímọbìnrin. Ayọ̀mídé Tòkunbọ̀ ṣùgbọ́n Olájùwọ́n Ariwódọlà ni ìyá rẹ̀ sọ́, Jùwọ́n náà ló sì tẹ̀ mọ lára. Inú bàbá Fẹ́mi bàjẹ́ nígbà tí ó rí bí Fẹ́mi ti dà ní London. Gbogbo bí ó ti rí àwọran Fẹ́mi tó ya fọ́tò pẹ̀lú Kúnbi, bí Kúnbi ṣe sọfún pé ayé ń ṣe’rú rẹ̀, tólóun yòó pe ọlọpàá fún òun àti bí ó ti sọ Fẹ́mi di gbèwùdání ni Olóyè rò fún ìyàwó rẹ̀. Wọ́n mọ Kúnbi torí òun ló ṣe ọ̀rẹ́ ìyàwó ní ọjọ́ ìgbéyàwó Ṣọlá. Ìyá Fẹ́mi figbe ta! Lẹ́yìn ò rẹyìn, wọ́n, Ìyawó olóyè, ìyẹn Ṣadé pinu àti lọ ri ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Ààfáà Akéulà lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ìyá Ṣọlá lọ kí ọmọ rẹ̀, ìyẹn sì sọfún nípa àwọn àlá tí ó ń lá. Ó sọ èyí tó lá kí Fẹ́mi tó lọ sí London fun. Ó tu sọ èyí tí ó lá fun ní ọjọ́ tí Fẹ́mi kọnu ìfẹ́ síi. Ó ní òun rí eni mímọ̀ òun kan tó ń rìn lọ pẹ̀lú Fẹ́mi, ẹni náà sì wọ bàtà òun, àmọ òun kò gbàgbó pé ẹni náà lè wọ bàtà òun láéláé. Màmá Ṣọlá náà rántí àlá tó lá, ló bá lo bá pásítọ̀. Lẹ́yìn èyí, Ṣọlá, ìyá rẹ̀ àti Pásítọ̀ ṣe àdúrà kárákára pẹ̀lú ìṣọ́ òru fún ọjọ́ méje. Ní àárọ̀ ọjọ́ kẹjọ, Ṣọlá lá àlá míràn mọ́jú. Nínú àlá náà, Ṣọlá lọ bá ẹnití ó wọ bàtà rẹ̀. Ẹni náà kò fẹ́ bọ àfi ìgbà tí owó kan fọ létí. Kía ló bá bàtà, tí ó sì ṣe rẹ́gí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó ní obìnrin náà fún òun ní okùn kan, ọrùn ọkọ rẹ̀ ní wọ́n fi wé. Kíá ló bọ lọ́rùn ọkọ rẹ̀, ni obìnrin náà bá ń ṣe wérewère. Àafáà Akéúlà náà ní kíwọ́n ṣe sààrá.

Lẹ́yìn oṣù mẹta tíwọn kò gbọ́ nǹkankan lọ́dọ̀ Fẹ́mi, Ṣọlá tún lọ bá pásítọ̀, ìyẹn sì sọfun pé kó ní sùúrù.