ṢÓKÍ ÌRAN KẸTA ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE THIRD SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

A ti fihàn ní ìran kíní pé ọmọ olówó ni Kúnbi, kò sì gbájú mọ́ ìwé rẹ̀ ní yunifasiti. Nínú ìran yìí, a ri kà pé bàbá rè, Olóyè Tẹjúmówó, ló ni ilé epo MOW. Bí tí ó ti ń gba atẹ́gùn níwájú ìta ni Kúnbi gbá ilẹ̀kùn gééti. Nígbàtí Áúdú, ìyẹn aṣọ́géétì ṣí géètì, tí ó rí Kúnbi ni ó ki, ṣùgbọ́n Kúnbi kò dáhún. Ó lọ bá Bàbá rẹ̀, ìyẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lati Àbújá ni, ó ṣì tún máa lọ patí. Ìyá ti bá ọrọ̀ ajé lọ Paris. Kúnbi pe ọmọ ọ̀dọ̀ wọn, Núra. Kò fèsì sí ìbéèrè tí ìyẹn bií, ó kàn pà ṣe fun ni pé kí ó lọ dáná fún oun. Ó kọjú sí bàbá rẹ̀, ó sì bèrè ẹgbẹrun lọ́nà aadọta (#50,000) lọ́wọ́ bàbá rẹ̀, ọ̀sẹ̀ méjì díẹ̀ sẹ́yìn nìyẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ fun ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà ọgbọn (#30,000). Bàbá rẹ̀ ṣe’lérí lati fun.

Inú Núrá ọmọ ọ̀dọ̀ kò dùn sí ìwà tí Kúnbi wù sì nítori ó dàgbà jù Kúnbi lọ dáadáa. Ibi tí ó ti ń ṣàròyé nínu ilé ìdáná ni Aṣọ́gbà dé ba. Wọ́n sì jọ ń sọ̀rọ̀ lóri ìbàjẹ́ àti ìmúra aṣéwó tí Kúnbi máa ń mú.