ṢÓKÍ ÌRAN KẸFÀ ÌWÉ WÀẸ́Ẹ̀KÌ ÀTI NÉKÒ Ọ̀RẸ́ MI TÍ ADÉRÍBÍGBÉ MORÓUNMÚBỌ̀ KỌ (SUMMARY OF THE SIXTH SCENE IN ADERIBIGBE MOROUNMUBO’S Ọ̀RẸ́ MI)

Hassan Abdulbaqi

Èrò pọ̀ gan-an níbi tíwọ́n ti lọ wo àfihàn sinimá Taxi Driver tí Adé Love ṣe. Ìtan ìfẹ́ láàrín ọkùnrin awakọ taxi kan àti ọmọ olówó kan ni eré náà dá lé lórí. Lọ́dọ̀ Ṣọlá, ìfẹ́ ló ṣe pàtàkì jù láàrín tọkọ taya, kìí ṣe owó. Bákan náà ni ó gbàgbọ́ pé tálákà òní lè padà da olówó lọla.

Lẹ́yìn tí Fẹ́mi àti Ṣọlá wo sinimá náà tán, wọn jọ lọ jẹun nílé olóúnjẹ kan. Ìgbà yìí gan ni Fẹ́mi tó sọfun nipa ìyáwó rẹ̀ àkọ́kọ́, tí o kú tòun àti oyún inú rẹ̀ bí ọdún máàrún sẹ́yìn. Ó sì ṣé lálàyé pé òun wá obìnrin rere bí Títí́layò, ìyàwó rẹ àkọ́kọ́. Ìdí nìyí tí òun kò tíì fẹ́ ìyàwó míràn.

Lẹ́yìn èyí ni Fẹ́mi dẹnu ìfẹ́ kọ, ó sì sọfún Ṣọlá kí ó má ape òun ní Fẹ́mi, kí ó máà pe òun ní Misita Johnson mọ́.   Ṣọlá ní kí Fẹ́mi fún òun ní ọ̀sẹ̀ kan lati ròó. Nígbà tí ó yá, Ṣọlá gbà fun. Inú Kúnbi kò dùn sí èyí rárá torí ó rò pé akúṣẹ ni Fẹ́mi. Gbogbo ìgbà tí  Fẹ́mi bá ti lọ kí Ṣọlá ni Kúnbi a máa sọ̀rọ̀ lóri bí àwọn olówó ṣe máa ń tọ́jú ìyàwó wọn. Fẹ́mi kò jẹ́ kí gbogbo ìwọ́sí wọ̀nyìí ba òun nínú jẹ́.