ṢÓKÍ ÌWÉ WAẸẸKI ÀTI NẸ́KÒ “Ọ̀RẸ́ MI” TÍ ADÉRÍBIGBÉ MORÓNMÚBỌ̀ MARTINA KỌ (SUMMARY OF YORUBA WAEC/NECO PRESCRIBED TEXT- ADERIBIGBE’S ỌRẸ MI (2)

Lati ọwọ́ Hassan Abdulbaqi

Ìran kejì fí yé wa pé tálákà ni Kọ́lá Ẹgbẹ́dá, bàbá Ṣolá. Ó kàwé díẹ̀, ó sì ń ṣiṣẹ́ ní rélùweè. Ìyá Ṣọlá ń se óúnjẹ tà ní ṣọ́ọ̀bù mẹkááníìkì lẹ́gbẹ wọn. Wọ́n bí ọkùnrin mẹ́ta (Ayọ̀, Káyòdé àti Kúnlé) àti obìnrin kan (Ṣọlá).

Nínú ìran yìí, Bàbá Ṣọlá ń dá sọ̀rọ̀ lórí ipò àìlówó rẹ̀ àti owó oṣù rẹ̀ tí ìjọba kò rí san. Bákan náà ni ó ń dúpẹ́ fún Ọlọ́hun fún ìyàwó atinilẹ́yìn àti àwọn ọmọ àrídun-nú tí Ọlọ́hun fun-un pàápàá jùlọ, Ṣọlá tí ó jẹ́ obinrin. Orí ọ̀rọ̀ yìí ni ó wà tí ìyàwó rẹ̀ fi wọlé. Ìyàwó rẹ̀ gbàá níyànjú kí ó má ṣe ronú mọ́ nítorí oun burúkú tí ìrònú máa ń dáá sílẹ̀ lára ènìyàn.Kódà, ó tún kìí ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí jẹun.

Níbi tí gbogbo wọn ti ń jẹun lọ́wọ́, Ṣọlá kan ilẹ̀kùn láìròtẹ́lẹ̀ nítorí ilé ìwé ló wà tẹ́lẹ̀. Wọ́n jọ jẹun papọ̀, nígbà tí ó yá ni Ṣọlá lọ bá bàbá rẹ̀ nínu ilé tí ó sì sọ ìdí tí ó fi wá sílé fun-un- ó nílò ẹgbẹ̀rún máàrún fún ìṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n fún won ní ilé ìwé lórí ọdún ìbílẹ̀ ní oríṣiríṣi ìlú. Ó ní òun ti rí ẹgbẹ̀rún méjì nínú rẹ̀ lati inú ọjà pẹ́pẹ̀pẹ́ tí òun ń tà, ó sì kun ẹgbẹ̀rún mẹ́ta kí ó pé.

Lẹ́yìn tí Ṣọlá kúrọ̀ lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, Bàbá àti Ìyá Ṣọlá sùn. Lẹ́yìn bí wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin ni Ìyá Ṣọlá ṣàdédé tají pẹ̀lú ìbẹ̀rù nítorí àlá burúkú tí ó lá. Ó jí Bàbá Ṣọlá, ó sì rọ́ àlá náà fun. Ó ní òun rí bàbá kan tí irun rẹ̀ funfun báláú, tí ó sí wọ aṣọ funfun kanlẹ̀. Ó gbé oúnje fún Ṣọlá tí ebí ń pa, Ṣolá sì ń gbé oúnjẹ náà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan náà ni ìjì gbé oúnjẹ́ yìí kúrò nínú àwo tí Ṣọlá sì bẹ̀rẹ̀ síí sunkún tí àwọn òbí rẹ̀ kò sì rí nǹkankan ṣe si.

Bàbá Ṣọlá sọfún aya rẹ̀ pé àlá lásán ni. Kò pé tí Bàbá Ṣọlá sùn lọ ni Ìyá Ṣọlá sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àdúrà.