OPÓ ALÀYÈ (WIDOW OF A LIVING HUSBAND)

Lati o̩wó̩ Ibrahim Òjó

 

Kò sóhun tó dùn léyò

Bí I kájí kára ó le

Kájìí-ǹ-de ara ó jé̩

È̩yin oko bángé tí ń han oóyó

E yá mi létí yín-ín

Kí baálé ó sojús̩e rè̩ nílé

Kó tó gba ibi is̩é̩ lo̩

K’áya ó tó̩jú ilé

Kó tún tó̩jú o̩mo̩

Ní í mú àlááfíà wá

Àlááfíà ò̩ún ìdùnnú

Ní í s̩ató̩kùn è̩mí gígùn

E̩ní láya ńlé ó tó̩jú wo̩n

Ò̩pò̩ aya ló ti dopó alàyè, dopó òjijì

O̩kùnrin tí kò s̩ojú s̩e rè̩ nílé̩

Òkú ayé ni’rú wo̩n

 

Ò̩pò̩ o̩ko̩ ni kò nání ilé mó̩

Tí Jagunlabí bá ti rí Sugar Mummy

Ohun tó ń s̩e wó̩n ti tán

Wó̩n á di bàbá rere bàbá kè nígboro

Aya á máa je̩ ìyà àjebólórí ló̩ò̩dè

Á máa dá gbé, dá fà lójú kan

 

Aya ní í sanwó ilé

Ohun ní í tún san ti ilé ìwé o̩mo̩

Bé̩e̩ bèrè o̩ko̩ ló̩wó̩ aya

Ìrònú yòó dé

Irú èsì wo ni e̩ fé̩ kí ó fò̩?

 

Kì í s̩e̩ni tó̩ko̩ rè̩ kú nìkan lo pó

O̩kùnrin tó kò̩ tí kò s̩ojús̩e rè̩ nílé

Òkú ayé ní í s̩e

Adìye wo̩n kò gbayì nílé mó̩

Iyì ìgboro ni wó̩n fi ń s̩ara ridin

Bé̩è̩, ilé la ti ń ké̩ s̩ò̩ó̩ ròde

 

K’édùmàrè gbà wá ló̩wó̩ è̩yin o̩ko̩ aláìlérò

E̩ té̩tí e̩ gbó̩ nàsíà yìí

Kí e̩ yéé saya dopó ayé

Bó pé títí té ò jáwó

È̩yin bàbá rere bàba kè̩ ìgboro

Àbámò̩ tó yé s̩áájú

Á padà wá gbè̩yìn ò̩rò̩

 

 

 

 

 

Posted in