BÍ ÌDÁNWÒ YORÙBÁ ÀṢEKAGBÁ (WAEC & NECO) RẸ YÒÓ ṢE RÍ)

Hassan Abdulbaqi

 

Bẹ́bà méjì ni aṣèdáńwò yòó dáhùn nínú ìdáńwò rẹ̀. Nínu bébà àkọ́kọ́, Ìbéèrè èwo-nìdáhùn (Multiple Choice questions) ni gbogbo ìbéèrè ọgọ́fà tí n bẹ nínú abala yìí yòó jẹ́. Bébà oníbéèrè èwo-nìdáhùn yìí yòó pín sí abala oríṣi mẹ́ta. Abala àkọ́kọ́ ni Èdè (Language), èyí tí yòó kún fún àyọkà (comprehension), ìró, gírámà àti ògbufọ̀ (translation). Abala èléèkejì ní í ṣe pèlú Lítíréṣò nígbàtí ẹ̀kẹta sì jẹmọ́ àṣà.

Bakan náà, bébà kejì pín sí abala mẹ́ta, ṣùgbọ́n kìí ṣe ìbéèrè èwo-nìdáhùn gẹ́gẹ́bí tí àkọ́kọ́. Ìbéèrè agbàròkọ (essay-type question) ni yòó jẹ́.  Ní abala àkọ́kọ́ tí ó jẹmọ́ ìlo èdè, akẹ́kọ̀ọ́ yòó dáhùn ìbéèrè lórí àròkọ (Onítàn, Aṣàpèjúwe, Lẹ́tà, Àríyànjiyàn, Alálàyé abbl), ìró (kọ́nsónántì, fáwélì, sílébù, ohùn abbl) àti gírámà (ìhun ọ̀rọ̀, gbólóhùn, awé gbólóhùn abbl).

Abala eléẹ̀kejì ni Lítíréṣọ̀ alohùn àti àp̣ílẹ̀kọ. Lábẹ́ Lítírésọ Alohùn, oríṣiríṣi ìwé mẹ́ta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn dá lórí Lítíréṣọ̀ ọlọ́rọ̀ geere, ewì àti eré oníṣe ni ìbéèrè kọ̀ọ̀kan yòó ti jẹyọ. Aṣèdánwó ní lati fẹ̀sì sí ọ̀kan péré nínu àwọn ìbéèrè yìí. Bákan náà ni ti lítíréṣọ̀ àpílẹ̀kọ. Abala tí ó parí náà ni abala èkéta èyí tí ó dá lórí àṣà (eré ayò, ìsọmọlórúkọ, ẹ̀kọ́ ilé, ogún pínpín, ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, ìgbágbó Yorùba abbl) ni ìbéèrè méjì yóò dá lé lórí tí àṣèdánwò yòó dáhùn eyọ kan nínú rẹ̀.

Eléyìí ni ṣókí bí ìdánwò àṣekágbà ṣe máa ń rí ní èdè Yorúba. Lágbára Alllahu Ràbí, a ó tún máa tèsíwájú nípa ṣí ṣe àlàyé lórí àwọn orí kọ̀ọ̀kan. Bákan náà, e kú ojú lọ́nà àwọn audio wa tí a tise ìgbohùn sílẹ àwọn ìwé Lítíréṣo tí à ń lò fún ìdánwò àṣekágbá Wàéèkì àti Nékò

Láyò o!