ÀWỌN ÒFIN TÍ Ń DE ÀKO̩TÓ̩ ÈDÈ YORÙBÁ
Hassan Abdulbaqi
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣemọ̀ tẹ́lẹ̀, a kò mọ àṣà mọ̀ọ́ kọ, mọ̀ọ́ kà mọ́ èdè Yorùbá lati ìṣèwá. Akitiyan àwọn òyìnbó gẹ́gẹ́bí E.T Bodwich, Hannah Kilham (1828) àti John Raban (1925) ló pilè kíkọ ède Yorùbá sílẹ̀. Oríṣiriṣi àyípadà ló sì ti débá àkọtọ́ ède Yorùbá lati ìgbà náà títí di 1975. Àkọtọ́ tí àwọn ìgbìmọ̀ àkọtọ́ èdè Yorùbá ṣe ni 1975 yìí là ń lò títí di òní. Ẹ̀kunrẹ́rẹ́ àlàyé lóri ìtàn bí àkọtọ́ èdè Yorùbá ṣe bẹ̀rẹ̀ títí di 1975 ṣì ń bọ̀ lọ̀ná.
Ohun tí mo fẹ́ kí a mú nínu orí yìí ni pé akẹ́kọọ tí ń gbaradì fún ìdánwò àṣekágbà gbọ̀dọ̀ mọ òfin àkọtọ́ 1975 yìí dájú, kí ó màá báá ṣòfọ̀ máàkì. Ìdí nìyìí tí màá fi fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn tó ń tànmàá àti máa kọ ní èdè Yorùbá ní àwọn òfin àkọ́tọ́ wọ̀nyìí.
- Àkọ́kọ́ nipé, èdè Yorùbá yàtọ̀ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, pààpàà jùlọ ní kíkọ. Bí a ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà ni à ń kọ́ ní èdè Yorùbá, èyí yàtọ̀ gedegbe sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nítorí lẹ́tà kan a máa ṣojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrọ́. Ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, lẹ́tà oríṣiriṣi lè ṣe aṣojú fún ìró kan. E jẹ́ kí a wo iró /k/ fún àpẹẹrẹ. A ri nínu ‘c’, ‘cc’, ‘ch’, ‘ck’, ‘k’ àti ‘q’ gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú àwọn lẹ́tà tí a falà sí wọ̀nyìí:
Coat, accord, chemistry, back, king, queen.
Báyìí kọ́ ni èdè Yorùbá rí. Bí a ṣé ń pe ọ̀rọ̀ náà ni à ń kọ́ọ́ sílẹ̀. Ìrọ́ /k/ a máa dúró fún létà ‘k’ nígbà òjò àti ẹ̀rùn ni. Bẹ̀ẹ́ nàá ló rí fún gbogbo àwọn ìrọ́ tókùn àti lẹ́tà tí wọ́n dúró fún. Ìdí nìyìí tí akẹ́kọ̀ọ́ gbọdọ̀ ṣọ́ra kúrò níbi àfikún ọ̀rọ̀ ní sípélì. Bakan náà ni kò gbọdọ̀ ṣe àdínkù.
Àwọn àkójọ́pọ̀ ọ̀rọ̀ tí irú àṣìṣe bàyìí ti máa ń wáyé àti àtúnṣe wọn ni:
Àṣìṣe Àtúnṣe
Aiyé Ayé
Ènìà Ènìyàn
Ọkọ̀nrin Ọkùnrin
Obìrin Obìnrin
Ẹiyẹ Ẹyẹ
Ẹnyin Ẹ̀yin
Nwọn Wọn
Míràn Mìíràn
Láíláí Láéláé
Yíò Yòó
Ọ̀ffà Ọ̀fà
- Lára àwọn òfin yìí ni pé kí a máa yán lẹ́tà “ṣ”
Àṣìṣe Àtúnṣe
Òshogbo Òṣogbo
Shọlá Ṣọlá
- Òmíràn nipé kí a máa lo lẹ́tà méjì dípò àmì fàágùn.
Àṣìkọ Àtúnṣe
Ōtó òótó
Ōrùn oòrun
- A kò gbọdọ̀ so ọ̀rọ̀ méjì papọ̀ àyàfi tí ìpàrójẹ (elision) bá wáyé láàrín wọn. Ìpàróje máa ń wáyé bí a bá yọ ìró tí ó wà nínu ọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ kúrò.
Ja olè — jalè
Fẹ́ ìyàwó —- fẹ́yàwò
A ti yọ àwọn ìró kan kúrò nínu àwọn ọ̀rọ̀ náà.
- A ní lati ya àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí sọ́tọ̀ ní kíkọ
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé
Wí pé
Jẹ́ kí
Wí pé
Èwo ni
Nígbà náà
Kí ni
Ta ni
Àwọn òfin tí ó rọ̀ mọ́ kíkọ́ èdè Yorùbá ṣì kù díẹ̀, a ó máa ṣàlàyé àwọn tókù lágbára Àlláhù Ràbí.